-
Lúùkù 11:29-32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Nígbà tí àwọn èrò ń kóra jọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ìran burúkú ni ìran yìí; ó ń wá àmì, àmọ́ a ò ní fún un ní àmì kankan àfi àmì Jónà.+ 30 Torí bí Jónà+ ṣe di àmì fún àwọn ará Nínéfè, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ èèyàn ṣe máa jẹ́ fún ìran yìí. 31 A máa gbé ọbabìnrin gúúsù+ dìde láti ṣèdájọ́ àwọn èèyàn ìran yìí, ó sì máa dá wọn lẹ́bi, torí ó wá láti ìkángun ayé kó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n Sólómọ́nì. Àmọ́ ẹ wò ó! ohun kan tó ju Sólómọ́nì lọ wà níbí.+ 32 Àwọn ará Nínéfè máa dìde láti ṣèdájọ́ ìran yìí, wọ́n á sì dá a lẹ́bi, torí pé wọ́n ronú pìwà dà nígbà tí Jónà wàásù fún wọn.+ Àmọ́ ẹ wò ó! ohun kan tó ju Jónà lọ wà níbí.
-