ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Máàkù 4:3-9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 “Ẹ fetí sílẹ̀. Ẹ wò ó! Afúnrúgbìn jáde lọ fún irúgbìn.+ 4 Bó ṣe ń fún irúgbìn, díẹ̀ já bọ́ sí etí ọ̀nà, àwọn ẹyẹ wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. 5 Àwọn míì já bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí iyẹ̀pẹ̀, wọ́n sì hù lójú ẹsẹ̀ torí pé iyẹ̀pẹ̀ náà ò jìn.+ 6 Àmọ́ nígbà tí oòrùn ràn, ó jó wọn gbẹ, wọ́n sì rọ torí pé wọn ò ní gbòǹgbò. 7 Àwọn irúgbìn míì já bọ́ sáàárín ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún náà yọ, wọ́n fún wọn pa, wọn ò sì so èso kankan.+ 8 Àmọ́ àwọn míì bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, wọ́n dàgbà, wọ́n pọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í so èso, wọ́n ń so ní ìlọ́po ọgbọ̀n (30), ọgọ́ta (60) àti ọgọ́rùn-ún (100).”+ 9 Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kí ẹni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”+

  • Lúùkù 8:4-8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Nígbà tí èrò rẹpẹtẹ ti kóra jọ pẹ̀lú àwọn tó ń lọ bá a láti ìlú dé ìlú, ó fi àpèjúwe kan sọ̀rọ̀,+ ó ní: 5 “Afúnrúgbìn kan jáde lọ fún irúgbìn rẹ̀. Bó ṣe ń fún irúgbìn, díẹ̀ lára rẹ̀ já bọ́ sí etí ọ̀nà, wọ́n tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ.+ 6 Àwọn kan já bọ́ sórí àpáta, lẹ́yìn tí wọ́n sì rú jáde, wọ́n gbẹ dà nù torí pé omi ò rin ibẹ̀.+ 7 Àwọn míì já bọ́ sáàárín ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún tí wọ́n sì jọ dàgbà fún wọn pa.+ 8 Àmọ́ àwọn míì já bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, lẹ́yìn tí wọ́n sì rú jáde, wọ́n so èso ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100).”+ Bó ṣe sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbóhùn sókè, ó ní: “Kí ẹni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́