22 Ní ti èyí tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, òun ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ tí àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí*+ àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso.+
18 Àwọn míì wà tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún. Àwọn yìí ló ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà,+19 àmọ́ àníyàn+ ètò àwọn nǹkan yìí,* agbára ìtannijẹ ọrọ̀+ àti ìfẹ́ + gbogbo nǹkan míì gbà wọ́n lọ́kàn, wọ́n fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso.
14 Ní ti àwọn tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, àwọn yìí ló gbọ́, àmọ́ torí pé àníyàn, ọrọ̀+ àti adùn ayé yìí + pín ọkàn wọn níyà, a fún wọn pa pátápátá, wọn ò sì mú kí ohunkóhun dàgbà.+