9 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í ní ohun tí àpèjúwe yìí túmọ̀ sí.+ 10 Ó sọ pé: “Ẹ̀yin la yọ̀ǹda fún pé kí ẹ lóye àwọn àṣírí mímọ́ Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ àpèjúwe+ ló jẹ́ fún àwọn yòókù, kó lè jẹ́ pé, bí wọ́n tiẹ̀ ń wò, lásán ni wọ́n á máa wò àti pé bí wọ́n tiẹ̀ ń gbọ́, kó má ṣe yé wọn.+