ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 6:9, 10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  9 Ó fèsì pé: “Lọ, kí o sì sọ fún àwọn èèyàn yìí pé:

      ‘Ẹ máa gbọ́ léraléra,

      Àmọ́ kò ní yé yín;

      Ẹ máa rí léraléra,

      Àmọ́ ẹ ò ní mọ nǹkan kan.’+

      10 Mú kí ọkàn àwọn èèyàn yìí yigbì,+

      Mú kí etí wọn di,+

      Kí o sì lẹ ojú wọn pọ̀,

      Kí wọ́n má bàa fi ojú wọn ríran,

      Kí wọ́n má sì fi etí wọn gbọ́rọ̀,

      Kí ọkàn wọn má bàa lóye,

      Kí wọ́n má bàa yí pa dà, kí wọ́n sì rí ìwòsàn.”+

  • Mátíù 13:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin la yọ̀ǹda fún pé kí ẹ lóye àwọn àṣírí mímọ́+ Ìjọba ọ̀run, àmọ́ a ò yọ̀ǹda fún wọn.

  • Mátíù 13:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ìdí nìyẹn tí mo fi ń fi àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀; torí ní ti bí wọ́n ṣe ń wò, lásán ni wọ́n ń wò, ní ti bí wọ́n ṣe ń gbọ́, lásán ni wọ́n ń gbọ́, kò sì yé wọn.+

  • Máàkù 4:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin la jẹ́ kó mọ àṣírí mímọ́+ Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ àpèjúwe ni gbogbo nǹkan jẹ́ fún àwọn tó wà ní òde,+ 12 kó lè jẹ́ pé, bí wọ́n tiẹ̀ ń wò, wọ́n lè máa wò, síbẹ̀ kí wọ́n má ṣe rí àti pé bí wọ́n tiẹ̀ ń gbọ́, wọ́n lè gbọ́, síbẹ̀ kó má sì yé wọn; wọn ò sì ní yí pa dà láé, kí wọ́n sì rí ìdáríjì.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́