-
Mátíù 13:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà sì ṣẹ sí wọn lára. Ó sọ pé: ‘Ó dájú pé ẹ máa gbọ́, àmọ́ kò ní yé yín rárá, ó sì dájú pé ẹ máa wò, àmọ́ ẹ ò ní ríran rárá.+
-
-
Ìṣe 28:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Tóò, nígbà tí èrò wọn ò ṣọ̀kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ibẹ̀ sílẹ̀, Pọ́ọ̀lù wá sọ ọ̀rọ̀ kan, ó ní:
“Ẹ̀mí mímọ́ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe wẹ́kú nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà fún àwọn baba ńlá yín, 26 pé, ‘Lọ sọ fún àwọn èèyàn yìí pé: “Ó dájú pé ẹ ó gbọ́, àmọ́ kò ní yé yín rárá; ó dájú pé ẹ ó wò, àmọ́ ẹ ò ní rí nǹkan kan.+
-