-
2 Àwọn Ọba 4:42-44Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
42 Ọkùnrin kan wá láti Baali-ṣálíṣà,+ ó sì kó ogún (20) búrẹ́dì ọkà bálì+ tí wọ́n fi àkọ́so èso ṣe àti àpò ọkà+ tuntun wá. Ìgbà náà ni Èlíṣà sọ pé: “Kó wọn fún àwọn èèyàn náà kí wọ́n lè jẹun.” 43 Síbẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Báwo ni màá ṣe gbé nǹkan yìí síwájú ọgọ́rùn-ún (100) èèyàn?”+ Ó fèsì pé: “Kó wọn fún àwọn èèyàn náà kí wọ́n lè jẹun, nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wọ́n á jẹ, á sì tún ṣẹ́ kù.’”+ 44 Ni ó bá gbé e síwájú wọn, wọ́n jẹ, ó sì tún ṣẹ́ kù+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà.
-
-
Lúùkù 9:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Torí náà, gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).+
-
-
Jòhánù 6:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Àmọ́ nígbà tí wọ́n yó, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kó àwọn ohun tó ṣẹ́ kù jọ, kí ohunkóhun má bàa ṣòfò.” 13 Torí náà, lẹ́yìn tí àwọn tó jẹ látinú búrẹ́dì ọkà báálì márùn-ún náà jẹun tán, wọ́n kó ohun tó ṣẹ́ kù jọ, ó sì kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).
-