28 Wọ́n wá mú Jésù látọ̀dọ̀ Káyáfà lọ sí ilé gómìnà.+ Àárọ̀ kùtù ni. Àmọ́ àwọn fúnra wọn ò wọnú ilé gómìnà, kí wọ́n má bàa sọ ara wọn di aláìmọ́,+ kí wọ́n lè jẹ Ìrékọjá.
28 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin náà mọ̀ dáadáa pé kò bófin mu rárá fún Júù láti dara pọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tó bá wá láti orílẹ̀-èdè míì tàbí kó wá sọ́dọ̀ rẹ̀,+ síbẹ̀ Ọlọ́run fi hàn mí pé kí n má ṣe pe èèyàn kankan ní ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́.+
2 Torí náà, nígbà tí Pétérù wá sí Jerúsálẹ́mù, àwọn tó ń ti ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́*+ lẹ́yìn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí rẹ̀,*3 wọ́n sọ pé: “O wọ ilé àwọn tí kò dádọ̀dọ́,* o sì bá wọn jẹun.”