32 Bí wọ́n ṣe ń lọ lójú ọ̀nà sí Jerúsálẹ́mù, Jésù ń lọ níwájú wọn, ẹnu yà wọ́n, àwọn tí wọ́n tẹ̀ lé e bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù. Ló bá tún pe àwọn Méjìlá náà sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn nǹkan tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí i fún wọn, ó ní:+
31 Ó wá pe àwọn Méjìlá náà sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, gbogbo nǹkan tí a tipasẹ̀ àwọn wòlíì kọ sílẹ̀ nípa Ọmọ èèyàn ló sì máa ṣẹ délẹ̀délẹ̀.*+