-
Mátíù 16:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Látìgbà yẹn lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí òun jìyà tó pọ̀ lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kí wọ́n sì pa òun, kí a sì jí òun dìde ní ọjọ́ kẹta.+
-
-
Mátíù 20:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá (12) náà sí ẹ̀gbẹ́ kan láwọn nìkan, ó sì sọ fún wọn lójú ọ̀nà pé:+ 18 “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì máa fa Ọmọ èèyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́. Wọ́n máa dájọ́ ikú fún un,+ 19 wọ́n sì máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ṣe yẹ̀yẹ́, kí wọ́n nà án, kí wọ́n sì kàn án mọ́gi;+ a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”+
-
-
Máàkù 10:32-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Bí wọ́n ṣe ń lọ lójú ọ̀nà sí Jerúsálẹ́mù, Jésù ń lọ níwájú wọn, ẹnu yà wọ́n, àwọn tí wọ́n tẹ̀ lé e bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù. Ló bá tún pe àwọn Méjìlá náà sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn nǹkan tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí i fún wọn, ó ní:+ 33 “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì máa fa Ọmọ èèyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́. Wọ́n máa dájọ́ ikú fún un, wọ́n sì máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, 34 àwọn yìí máa fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n máa tutọ́ sí i lára, wọ́n máa nà án, wọ́n á sì pa á, àmọ́ ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ló máa dìde.”+
-