-
Mátíù 16:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Látìgbà yẹn lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí òun jìyà tó pọ̀ lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kí wọ́n sì pa òun, kí a sì jí òun dìde ní ọjọ́ kẹta.+
-
-
Máàkù 10:33, 34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì máa fa Ọmọ èèyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́. Wọ́n máa dájọ́ ikú fún un, wọ́n sì máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, 34 àwọn yìí máa fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n máa tutọ́ sí i lára, wọ́n máa nà án, wọ́n á sì pa á, àmọ́ ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ló máa dìde.”+
-