-
Máàkù 11:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ Jerúsálẹ́mù, Bẹtifágè àti Bẹ́tánì + ní Òkè Ólífì, ó rán méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde,+ 2 ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú abúlé ọ̀ọ́kán yìí, bí ẹ bá ṣe ń wọ ibẹ̀, ẹ máa rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* kan tí wọ́n so, èyí tí èèyàn kankan ò jókòó lé rí títí di báyìí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú un wá síbí. 3 Tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe èyí?’ kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa fẹ́ lò ó, ó sì máa fi ránṣẹ́ pa dà síbí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.’”
-
-
Lúùkù 19:28-31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, ó ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. 29 Nígbà tó sún mọ́ Bẹtifágè àti Bẹ́tánì, ní òkè tí wọ́n ń pè ní Òkè Ólífì,+ ó rán méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn jáde,+ 30 ó sọ pé: “Ẹ lọ sínú abúlé ọ̀ọ́kán yìí, tí ẹ bá sì ti wọ ibẹ̀, ẹ máa rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* kan tí wọ́n so, èyí tí èèyàn kankan ò jókòó lé rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú un wá síbí. 31 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tú u?’ kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa fẹ́ lò ó.’”
-