-
Mátíù 21:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Nígbà tí wọ́n sún mọ́ Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì dé Bẹtifágè lórí Òkè Ólífì, Jésù rán ọmọ ẹ̀yìn méjì jáde,+ 2 ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú abúlé ọ̀ọ́kán yìí, gbàrà tí ẹ bá débẹ̀, ẹ máa rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. 3 Tí ẹnì kan bá bá yín sọ ohunkóhun, kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa fẹ́ lò wọ́n.’ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló máa fi wọ́n ránṣẹ́.”
-
-
Lúùkù 19:29-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Nígbà tó sún mọ́ Bẹtifágè àti Bẹ́tánì, ní òkè tí wọ́n ń pè ní Òkè Ólífì,+ ó rán méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn jáde,+ 30 ó sọ pé: “Ẹ lọ sínú abúlé ọ̀ọ́kán yìí, tí ẹ bá sì ti wọ ibẹ̀, ẹ máa rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* kan tí wọ́n so, èyí tí èèyàn kankan ò jókòó lé rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú un wá síbí. 31 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tú u?’ kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa fẹ́ lò ó.’” 32 Torí náà, àwọn tó rán níṣẹ́ lọ, wọ́n sì rí i bó ṣe sọ fún wọn gẹ́lẹ́.+ 33 Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn tó ni ín sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yẹn?” 34 Wọ́n sọ pé: “Olúwa fẹ́ lò ó.”
-