-
Lúùkù 3:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn èrò tó ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ṣèrìbọmi pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, ta ló kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ sá fún ìbínú tó ń bọ̀?+ 8 Torí náà, ẹ so èso tó yẹ ìrònúpìwàdà. Ẹ má bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ara yín pé, ‘A ní Ábúráhámù ní baba.’ Torí mò ń sọ fún yín pé Ọlọ́run lè gbé àwọn ọmọ dìde fún Ábúráhámù látinú àwọn òkúta yìí. 9 Ó dájú pé àáké ti wà níbi gbòǹgbò àwọn igi báyìí. Torí náà, gbogbo igi tí kò bá so èso tó dáa la máa gé lulẹ̀, tí a sì máa jù sínú iná.”+
-
-
Lúùkù 21:23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Ó mà ṣe o, fún àwọn aláboyún àti àwọn tó ń tọ́ ọmọ jòjòló ní àwọn ọjọ́ yẹn o!+ Torí wàhálà ńlá máa bá ilẹ̀ náà, ìbínú sì máa wá sórí àwọn èèyàn yìí.
-