-
Mátíù 7:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere la máa gé lulẹ̀, tí a sì máa jù sínú iná.+
-
-
Lúùkù 13:6-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ó wá sọ àpèjúwe yìí, ó ní: “Ọkùnrin kan gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀, ó sì wá síbẹ̀, ó ń wá èso lórí rẹ̀, àmọ́ kò rí ìkankan.+ 7 Ó wá sọ fún ẹni tó ń rẹ́wọ́ àjàrà pé, ‘Ó ti pé ọdún mẹ́ta báyìí tí mo ti ń wá síbí, tí mò ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, àmọ́ mi ò rí ìkankan. Gé e lulẹ̀! Ṣe ló kàn ń fi ilẹ̀ ṣòfò lásán.’ 8 Ó dá a lóhùn pé, ‘Ọ̀gá, jẹ́ kó lo ọdún kan sí i, títí màá fi gbẹ́lẹ̀ yí i ká, tí màá sì fi ajílẹ̀ sí i. 9 Tó bá so èso lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn dáa; àmọ́ tí kò bá so, o lè wá gé e lulẹ̀.’”+
-