ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Máàkù 12:13-17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Lẹ́yìn náà, wọ́n rán àwọn kan lára àwọn Farisí àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù lọ bá a, kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un.+ 14 Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n sọ fún un pé: “Olùkọ́, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, o kì í wá ojúure ẹnikẹ́ni, torí kì í ṣe ìrísí àwọn èèyàn lò ń wò, àmọ́ ò ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́. Ṣé ó bófin mu* láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu? 15 Ṣé ká san án àbí ká má san án?” Ó rí i pé alágàbàgebè ni wọ́n, ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń dán mi wò? Ẹ mú owó dínárì* kan wá fún mi kí n wò ó.” 16 Wọ́n mú ọ̀kan wá, ó sì sọ fún wọn pé: “Àwòrán àti àkọlé ta nìyí?” Wọ́n sọ fún un pé: “Ti Késárì ni.” 17 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì,+ àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ Ẹnu sì yà wọ́n sí i.

  • Lúùkù 20:20-26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Lẹ́yìn tí wọ́n ṣọ́ ọ dáadáa, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tí wọ́n háyà ní bòókẹ́lẹ́ jáde pé kí wọ́n díbọ́n pé àwọn jẹ́ olódodo, kí wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un,+ kí wọ́n lè fà á lé ìjọba lọ́wọ́, kí wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ gómìnà. 21 Wọ́n bi í pé: “Olùkọ́, a mọ̀ pé o máa ń sọ̀rọ̀, o sì máa ń kọ́ni lọ́nà tó tọ́, o kì í ṣe ojúsàájú rárá, àmọ́ ò ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́: 22 Ṣé ó bófin mu* fún wa láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu?” 23 Àmọ́ ó rí i pé alárèékérekè ni wọ́n, ó wá sọ fún wọn pé: 24 “Ẹ fi owó dínárì* kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ta ló wà níbẹ̀?” Wọ́n sọ pé: “Ti Késárì.” 25 Ó sọ fún wọn pé: “Torí náà, ẹ rí i dájú pé ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì,+ àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ 26 Wọn ò wá lè fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un níwájú àwọn èèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀, ìdáhùn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì dákẹ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́