5 Lẹ́yìn náà, nígbà tí àwọn kan ń sọ̀rọ̀ nípa tẹ́ńpìlì, bí wọ́n ṣe fi òkúta tó rẹwà àti àwọn ohun tí a yà sí mímọ́ ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,+ 6 ó sọ pé: “Ní ti àwọn nǹkan yìí tí ẹ̀ ń rí báyìí, ọjọ́ ń bọ̀ tí wọn ò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta míì láìwó o palẹ̀.”+