-
Lúùkù 4:9-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Lẹ́yìn náà, ó mú un lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó mú un dúró lórí ògiri orí òrùlé* tẹ́ńpìlì, ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ láti ibí yìí,+ 10 torí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó máa pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ, pé kí wọ́n pa ọ́ mọ́’ 11 àti pé, ‘Wọ́n á fi ọwọ́ wọn gbé ọ, kí o má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbá òkúta.’”+ 12 Jésù dá a lóhùn pé: “A sọ ọ́ pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà* Ọlọ́run rẹ wò.’”+
-