-
Mátíù 4:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Lẹ́yìn náà, Èṣù mú un lọ sí ìlú mímọ́,+ ó mú un dúró lórí ògiri orí òrùlé* tẹ́ńpìlì,+ 6 ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀, torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Ó máa pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ’ àti pé ‘Wọ́n á fi ọwọ́ wọn gbé ọ, kí o má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbá òkúta.’”+ 7 Jésù sọ fún un pé: “A tún ti kọ ọ́ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà* Ọlọ́run rẹ wò.’”+
-