-
Máàkù 14:32-36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Wọ́n wá dé ibì kan tí wọ́n ń pè ní Gẹ́tísémánì, ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jókòó síbí, kí èmi máa gbàdúrà.”+ 33 Ó mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù dání pẹ̀lú rẹ̀,+ ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ní ẹ̀dùn ọkàn gidigidi,* ìdààmú sì bá a gan-an. 34 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi* gan-an,+ àní títí dé ikú. Ẹ dúró síbí, kí ẹ sì máa ṣọ́nà.”+ 35 Ó lọ síwájú díẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà pé, tó bá ṣeé ṣe, kí wákàtí náà ré òun kọjá. 36 Ó sì sọ pé: “Ábà,* Bàbá,+ ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ọ; mú ife yìí kúrò lórí mi. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tí èmi fẹ́, àmọ́ ohun tí ìwọ fẹ́.”+
-
-
Lúùkù 22:40Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
40 Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.”+
-