-
Máàkù 14:37-42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
37 Ó pa dà wá, ó sì rí i pé wọ́n ń sùn, ó wá sọ fún Pétérù pé: “Símónì, ò ń sùn ni? Ṣé o ò lókun láti ṣọ́nà fún wákàtí kan ni?+ 38 Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.+ Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń fẹ́,* àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.”+ 39 Ó tún lọ gbàdúrà, ó ń sọ ohun kan náà.+ 40 Ó tún pa dà wá, ó sì rí i pé wọ́n ń sùn, torí oorun ń kùn wọ́n gan-an, torí náà, wọn ò mọ èsì tí wọ́n máa fún un. 41 Ó pa dà wá lẹ́ẹ̀kẹta, ó sì sọ fún wọn pé: “Ní irú àkókò yìí, ẹ̀ ń sùn, ẹ sì ń sinmi! Ó tó! Wákàtí náà ti dé!+ Ẹ wò ó! A fi Ọmọ èèyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 42 Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká lọ. Ẹ wò ó! Ẹni tó máa dà mí ti dé tán.”+
-
-
Lúùkù 22:45Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
45 Nígbà tó dìde níbi tó ti ń gbàdúrà, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì bá wọn tí wọ́n ń tòògbé, ẹ̀dùn ọkàn ti mú kó rẹ̀ wọ́n gan-an.+
-