17 Èlíṣà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, ó sọ pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́, la ojú rẹ̀, kó lè ríran.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì ríran, wò ó! àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun oníná+ kún agbègbè olókè náà, wọ́n sì yí Èlíṣà ká.+
10 Iná ń ṣàn jáde lọ níwájú rẹ̀.+ Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì dúró níwájú rẹ̀.+ Kọ́ọ̀tù+ jókòó, a sì ṣí àwọn ìwé.