-
Máàkù 15:29-32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Àwọn tó ń kọjá lọ ń bú u, wọ́n sì ń mi orí wọn,+ wọ́n ń sọ pé: “Ṣíọ̀! Ìwọ tí o fẹ́ wó tẹ́ńpìlì palẹ̀, kí o sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ,+ 30 gba ara rẹ là, kí o sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó igi oró.”* 31 Bákan náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ láàárín ara wọn, wọ́n ń sọ pé: “Ó gba àwọn ẹlòmíì là; kò lè gba ara rẹ̀ là!+ 32 Kí Kristi, Ọba Ísírẹ́lì sọ̀ kalẹ̀ látorí òpó igi oró,* ká lè rí i, ká sì gbà gbọ́.”+ Àwọn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pàápàá ń fi ṣe ẹlẹ́yà.+
-