ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 8:30-33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ tó pọ̀ ń jẹun+ níbì kan tó jìnnà sọ́dọ̀ wọn. 31 Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé: “Tí o bá lé wa jáde, jẹ́ ká wọnú ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ yẹn.”+ 32 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ!” Ni wọ́n bá jáde, wọ́n sì wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, wò ó! gbogbo ọ̀wọ́ ẹran náà rọ́ kọjá ní etí òkè* sínú òkun, wọ́n sì kú sínú omi. 33 Àwọn darandaran bá sá lọ, nígbà tí wọ́n dé inú ìlú, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀, títí kan ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà.

  • Lúùkù 8:32-34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀+ tó pọ̀ ń jẹun níbẹ̀ lórí òkè náà, torí náà, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó gba àwọn láyè láti wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ó sì gbà wọ́n láyè.+ 33 Ni àwọn ẹ̀mí èṣù náà bá jáde lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ọ̀wọ́ ẹran náà rọ́ kọjá ní etí òkè* sínú adágún, wọ́n sì kú sínú omi. 34 Àmọ́ nígbà tí àwọn darandaran rí ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá lọ, wọ́n sì ròyìn rẹ̀ nínú ìlú àti ní ìgbèríko.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́