-
Mátíù 8:30-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ tó pọ̀ ń jẹun+ níbì kan tó jìnnà sọ́dọ̀ wọn. 31 Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé: “Tí o bá lé wa jáde, jẹ́ ká wọnú ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ yẹn.”+ 32 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ!” Ni wọ́n bá jáde, wọ́n sì wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, wò ó! gbogbo ọ̀wọ́ ẹran náà rọ́ kọjá ní etí òkè* sínú òkun, wọ́n sì kú sínú omi. 33 Àwọn darandaran bá sá lọ, nígbà tí wọ́n dé inú ìlú, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀, títí kan ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà. 34 Wò ó! gbogbo ìlú jáde wá pàdé Jésù, nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó kúrò ní agbègbè wọn.+
-
-
Máàkù 5:11-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀+ tó pọ̀ ń jẹun níbẹ̀ níbi òkè.+ 12 Torí náà, àwọn ẹ̀mí náà bẹ̀ ẹ́ pé: “Lé wa lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ká lè wọnú wọn.” 13 Torí náà, ó gbà wọ́n láyè. Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bá jáde, wọ́n sì wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ọ̀wọ́ ẹran náà rọ́ kọjá ní etí òkè* sínú òkun, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ni wọ́n, wọ́n sì kú sínú òkun. 14 Àmọ́ àwọn tó ń dà wọ́n sá lọ, wọ́n sì ròyìn rẹ̀ nínú ìlú àti ní ìgbèríko, àwọn èèyàn sì wá wo ohun tó ṣẹlẹ̀.+ 15 Torí náà, wọ́n wá bá Jésù, wọ́n sì rí ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà, ẹni tí líjíónì wà nínú rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó jókòó, ó ti wọṣọ, orí rẹ̀ sì ti wálé, ni ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. 16 Bákan náà, àwọn tí wọ́n rí i ròyìn fún wọn nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà àti àwọn ẹlẹ́dẹ̀. 17 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jésù pé kó kúrò ní agbègbè wọn.+
-