42 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà pòórá lára rẹ̀, ó sì mọ́. 43 Ó wá kìlọ̀ fún un gidigidi, ó sì ní kó máa lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, 44 ó sọ fún un pé: “Rí i pé o ò sọ nǹkan kan fún ẹnikẹ́ni, àmọ́ lọ fi ara rẹ han àlùfáà, kí o sì mú àwọn ohun tí Mósè sọ dání láti wẹ̀ ọ́ mọ́,+ kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”+