Mátíù 6:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Àmọ́ tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ, lẹ́yìn tí o bá ti ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tó wà ní ìkọ̀kọ̀.+ Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san. Mátíù 14:23 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 23 Lẹ́yìn tó ní kí àwọn èrò náà máa lọ, òun nìkan lọ sórí òkè láti gbàdúrà.+ Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, òun nìkan ló wà níbẹ̀. Máàkù 1:35 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 35 Ní àárọ̀ kùtù, tí ilẹ̀ ò tíì mọ́, ó dìde, ó jáde lọ síbi tó dá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà níbẹ̀.+ Lúùkù 6:12 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 12 Nígbà yẹn, ó lọ sórí òkè lọ́jọ́ kan láti gbàdúrà,+ ó sì fi gbogbo òru gbàdúrà sí Ọlọ́run.+
6 Àmọ́ tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ, lẹ́yìn tí o bá ti ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tó wà ní ìkọ̀kọ̀.+ Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san.
23 Lẹ́yìn tó ní kí àwọn èrò náà máa lọ, òun nìkan lọ sórí òkè láti gbàdúrà.+ Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, òun nìkan ló wà níbẹ̀.