-
Mátíù 14:24-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Ní àkókò yẹn, ọkọ̀ ojú omi náà ti wà ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwọ̀n yáàdì* sí orí ilẹ̀, wọ́n ń bá ìgbì òkun fà á, torí pé atẹ́gùn náà ń dà wọ́n láàmú. 25 Àmọ́ ní ìṣọ́ kẹrin òru,* ó wá bá wọn, ó ń rìn lórí òkun. 26 Nígbà tí wọ́n tajú kán rí i tó ń rìn lórí òkun, ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò balẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ìran abàmì nìyí!” Wọ́n bá kígbe torí ẹ̀rù bà wọ́n. 27 Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ́kàn le! Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”+ 28 Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, tó bá jẹ́ ìwọ ni, pàṣẹ fún mi pé kí n wá bá ọ lórí omi.” 29 Ó sọ pé: “Máa bọ̀!” Pétérù wá jáde nínú ọkọ̀ ojú omi, ó rìn lórí omi, ó sì ń lọ sọ́dọ̀ Jésù. 30 Àmọ́ nígbà tó wo ìjì tó ń jà, ẹ̀rù bà á. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í rì, ó ké jáde pé: “Olúwa, gbà mí!” 31 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì dì í mú, ó sọ fún un pé: “Ìwọ tí ìgbàgbọ́ rẹ kéré, kí ló dé tí o fi ṣiyèméjì?”+ 32 Lẹ́yìn tí wọ́n wọnú ọkọ̀ ojú omi náà, ìjì tó ń jà rọlẹ̀. 33 Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà wá tẹrí ba* fún un, wọ́n sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ọ́ lóòótọ́.”
-
-
Jòhánù 6:16-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí òkun,+ 17 wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì forí lé Kápánáúmù. Ilẹ̀ ti wá ṣú báyìí, Jésù ò sì tíì wá bá wọn.+ 18 Bákan náà, òkun ti ń ru gùdù torí pé ìjì líle kan ń fẹ́.+ 19 Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti tukọ̀ tó nǹkan bíi máìlì mẹ́ta sí mẹ́rin,* wọ́n rí Jésù tó ń rìn lórí òkun, tó sì ń sún mọ́ ọkọ̀ ojú omi náà, ẹ̀rù sì bà wọ́n. 20 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù!”+ 21 Ìgbà yẹn ni wọ́n wá fẹ́ kó wọnú ọkọ̀ ojú omi náà, ọkọ̀ ojú omi náà sì dé ilẹ̀ tí wọ́n forí lé+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
-