Jẹ́nẹ́sísì 6:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 Jèhófà wá rí i pé ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an ní ayé, ó sì rí i pé kìkì ohun búburú ló ń rò lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.+ Jẹ́nẹ́sísì 8:21 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 21 Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ òórùn dídùn.* Jèhófà wá sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Mi ò tún ní fi ilẹ̀+ gégùn-ún* mọ́ torí èèyàn, torí pé kìkì ibi ni èèyàn ń rò lọ́kàn láti ìgbà èwe rẹ̀ wá;+ mi ò sì tún ní pa gbogbo ohun alààyè run mọ́, bí mo ti ṣe.+ Jeremáyà 17:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Ọkàn ń tanni jẹ* ju ohunkóhun lọ, kò sóhun tí kò lè ṣe.*+ Ta ló lè mọ̀ ọ́n?
5 Jèhófà wá rí i pé ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an ní ayé, ó sì rí i pé kìkì ohun búburú ló ń rò lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.+
21 Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ òórùn dídùn.* Jèhófà wá sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Mi ò tún ní fi ilẹ̀+ gégùn-ún* mọ́ torí èèyàn, torí pé kìkì ibi ni èèyàn ń rò lọ́kàn láti ìgbà èwe rẹ̀ wá;+ mi ò sì tún ní pa gbogbo ohun alààyè run mọ́, bí mo ti ṣe.+