49 Òṣìṣẹ́ ọba náà sọ fún un pé: “Olúwa, sọ̀ kalẹ̀ wá kí ọmọ mi kékeré tó kú.” 50 Jésù sọ fún un pé: “Máa lọ; ọmọ rẹ ti yè.”+ Ọkùnrin náà gba ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún un gbọ́, ó sì lọ. 51 Àmọ́ bó ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ lọ, àwọn ẹrú rẹ̀ pàdé rẹ̀ kí wọ́n lè sọ fún un pé ọmọ rẹ̀ ti yè.