ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 16:5-12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọdá sí òdìkejì, wọn ò sì rántí mú búrẹ́dì dání.+ 6 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”+ 7 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó láàárín ara wọn pé: “A ò mú búrẹ́dì kankan dání.” 8 Jésù mọ èyí, ó wá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sọ láàárín ara yín pé ẹ ò ní búrẹ́dì, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? 9 Ṣé ọ̀rọ̀ yẹn ò tíì yé yín ni, àbí ẹ ò rántí búrẹ́dì márùn-ún tí mo fi bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) àti iye apẹ̀rẹ̀ tí ẹ kó jọ?+ 10 Àbí búrẹ́dì méje tí mo fi bọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) àti iye apẹ̀rẹ̀ ńlá* tí ẹ kó jọ?+ 11 Kí nìdí tí kò fi yé yín pé ọ̀rọ̀ búrẹ́dì kọ́ ni mò ń bá yín sọ? Àmọ́, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”+ 12 Ìgbà yẹn ló wá yé wọn pé kì í ṣe ìwúkàrà búrẹ́dì ló ní kí wọ́n ṣọ́ra fún, ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti àwọn Sadusí ni.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́