27 Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá lọ sí àwọn abúlé Kesaríà Fílípì, ó sì ń bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú ọ̀nà pé: “Ta ni àwọn èèyàn ń sọ pé mo jẹ́?”+ 28 Wọ́n sọ fún un pé: “Jòhánù Arinibọmi,+ àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà,+ àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan lára àwọn wòlíì.”