-
Mátíù 17:14-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn èrò,+ ọkùnrin kan wá bá a, ó kúnlẹ̀ fún un, ó sì sọ pé: 15 “Olúwa, ṣàánú ọmọkùnrin mi, torí ó ní wárápá, ara rẹ̀ ò sì yá. Ó máa ń ṣubú sínú iná àti sínú omi lọ́pọ̀ ìgbà.+ 16 Mo mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ, àmọ́ wọn ò lè wò ó sàn.” 17 Jésù fèsì pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́ àti oníbékebèke,+ títí dìgbà wo ni màá fi wà pẹ̀lú yín? Títí dìgbà wo ni màá fi máa fara dà á fún yín? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níbí.”
-
-
Lúùkù 9:38-42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 Wò ó! ọkùnrin kan ké jáde láti àárín èrò náà pé: “Olùkọ́, mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọkùnrin mi, torí òun nìkan ṣoṣo ni mo bí.+ 39 Wò ó! ẹ̀mí kan máa ń gbé e, á sì kígbe lójijì, á fi gìrì mú un, á sì máa yọ ìfófòó lẹ́nu, agbára káká ló fi máa ń fi í sílẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti ṣe é léṣe. 40 Mo bẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ pé kí wọ́n lé e jáde, àmọ́ wọn ò lè ṣe é.” 41 Jésù fèsì pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́ àti oníbékebèke,+ títí dìgbà wo ni màá fi wà pẹ̀lú yín, tí màá sì máa fara dà á fún yín? Mú ọmọkùnrin rẹ wá síbí.”+ 42 Àmọ́ bó ṣe ń sún mọ́ tòsí pàápàá, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì fi gìrì mú un lọ́nà tó le gan-an. Ṣùgbọ́n Jésù bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó wo ọmọ náà sàn, ó sì dá a pa dà fún bàbá rẹ̀.
-