-
Máàkù 9:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ọ̀kan lára àwọn èrò náà dá a lóhùn pé: “Olùkọ́, mo mú ọmọkùnrin mi wá sọ́dọ̀ rẹ torí ó ní ẹ̀mí kan tí kò jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀.+ 18 Ní ibikíbi tó bá ti mú un, ṣe ló máa ń gbé e ṣánlẹ̀, á sì máa yọ ìfófòó lẹ́nu, á máa wa eyín pọ̀, kò sì ní lókun mọ́. Mo ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ lé e jáde, àmọ́ wọn ò rí i ṣe.”
-