ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 21:33-41
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 “Ẹ gbọ́ àpèjúwe míì: Ọkùnrin kan wà, ó ní ilẹ̀, ó gbin àjàrà, ó sì ṣe ọgbà yí i ká,+ ó gbẹ́ ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì sínú rẹ̀, ó sì kọ́ ilé gogoro kan;+ ó wá gbé e fún àwọn tó ń dáko, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.+ 34 Nígbà tó di àsìkò tí èso ń so, ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń dáko náà pé kí wọ́n gba àwọn èso rẹ̀ wá. 35 Àmọ́ àwọn tó ń dáko náà mú àwọn ẹrú rẹ̀, wọ́n lu ọ̀kan nílùkulù, wọ́n pa ìkejì, wọ́n sì sọ òmíràn lókùúta.+ 36 Ó tún rán àwọn ẹrú míì, tí wọ́n pọ̀ ju àwọn ti àkọ́kọ́ lọ, àmọ́ ohun kan náà ni wọ́n ṣe sí àwọn yìí.+ 37 Níkẹyìn, ó rán ọmọ rẹ̀ sí wọn, ó ní, ‘Wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ọmọ mi.’ 38 Nígbà tí wọ́n rí ọmọ náà, àwọn tó ń dáko náà sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹni tó máa jogún rẹ̀ nìyí.+ Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká pa á, ká sì gba ogún rẹ̀!’ 39 Torí náà, wọ́n mú un, wọ́n jù ú sí ìta ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.+ 40 Tí ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà bá wá dé, kí ló máa ṣe fún àwọn tó ń dáko yẹn?” 41 Wọ́n sọ fún un pé: “Torí pé èèyàn burúkú ni wọ́n, ó máa mú ìparun tó lágbára* wá sórí wọn, ó sì máa gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn míì tó ń dáko, tí wọ́n máa fún un ní èso nígbà tí àkókò bá tó.”

  • Lúùkù 20:9-16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àpèjúwe yìí fún àwọn èèyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin àjàrà,+ ó gbé e fún àwọn tó ń dáko, ó sì rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fúngbà díẹ̀.+ 10 Nígbà tí àsìkò tó, ó rán ẹrú kan lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń dáko náà, kí wọ́n lè fún un lára èso ọgbà àjàrà náà. Àmọ́ àwọn tó ń dáko náà lù ú, wọ́n sì ní kó máa lọ lọ́wọ́ òfo.+ 11 Àmọ́ ó tún rán ẹrú míì. Wọ́n lu ìyẹn náà, wọ́n dójú tì í,* wọ́n sì ní kó máa lọ lọ́wọ́ òfo. 12 Ó tún rán ẹnì kẹta; wọ́n ṣe ẹni yìí náà léṣe, wọ́n sì jù ú síta. 13 Ni ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà bá sọ pé, ‘Kí ni kí n ṣe? Màá rán ọmọ mi ọ̀wọ́n.+ Ó ṣeé ṣe kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún un.’ 14 Nígbà tí àwọn tó ń dáko náà tajú kán rí i, wọ́n rò ó láàárín ara wọn pé, ‘Ẹni tó máa jogún rẹ̀ nìyí. Ẹ jẹ́ ká pa á, kí ogún náà lè di tiwa.’ 15 Torí náà, wọ́n jù ú sí ìta ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.+ Kí ni ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà máa wá ṣe sí wọn? 16 Ó máa wá, ó máa pa àwọn tó ń dáko yìí, á sì gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn míì.”

      Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n sọ pé: “Kí ìyẹn má ṣẹlẹ̀ láé!”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́