31 Bákan náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn pé Ọmọ èèyàn gbọ́dọ̀ jìyà púpọ̀, àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin máa kọ̀ ọ́, wọ́n máa pa á,+ ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ló sì máa dìde.+
10 kí gbogbo yín àti gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì yáa mọ̀ pé ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárẹ́tì,+ ẹni tí ẹ kàn mọ́gi,*+ àmọ́ tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú ikú,+ ni ọkùnrin yìí fi dúró níbí pẹ̀lú ara yíyá gágá níwájú yín.