-
Mátíù 11:7-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Nígbà tí àwọn yìí ń lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn èrò náà nípa Jòhánù pé: “Kí lẹ jáde lọ wò ní aginjù?+ Ṣé esùsú* tí atẹ́gùn ń gbé kiri ni?+ 8 Kí wá lẹ jáde lọ wò? Ṣé ọkùnrin tó wọ aṣọ àtàtà* ni? Ṣebí inú ilé àwọn ọba ni àwọn tó wọ aṣọ àtàtà máa ń wà? 9 Ká sòótọ́, kí ló wá dé tí ẹ jáde lọ? Ṣé kí ẹ lè rí wòlíì ni? Àní mo sọ fún yín, ó ju wòlíì lọ dáadáa.+ 10 Ẹni yìí la kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi ṣáájú rẹ,* ẹni tó máa ṣètò ọ̀nà rẹ dè ọ́!’+ 11 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, nínú àwọn tí obìnrin bí, kò tíì sí ẹni tó tóbi ju Jòhánù Arinibọmi lọ, àmọ́ ẹni kékeré nínú Ìjọba ọ̀run tóbi jù ú lọ.+
-