3Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé: “Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi, á sì tún ọ̀nà ṣe* dè mí.+ Lójijì, Olúwa tòótọ́, ẹni tí ẹ̀ ń wá yóò wá sí tẹ́ńpìlì rẹ̀;+ ìránṣẹ́ májẹ̀mú yóò sì wá, ẹni tí inú yín dùn sí. Wò ó! Ó dájú pé ó máa wá.
17 Bákan náà, ó máa lọ ṣáájú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí àti agbára Èlíjà,+ kó lè yí ọkàn àwọn bàbá pa dà sí àwọn ọmọ+ àti àwọn aláìgbọràn sí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ ti àwọn olódodo, kó lè ṣètò àwọn èèyàn tí a ti múra sílẹ̀ fún Jèhófà.”*+