46 Ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bá fi ìgboyà sọ fún wọn pé: “Ó pọn dandan pé ẹ̀yin ni kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún.+ Nígbà tí ẹ sì ti kọ̀ ọ́, tí ẹ ò ka ara yín sí ẹni tó yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, torí náà, a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè.+
2 Nítorí mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run,+ àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ tó péye. 3 Bí wọn ò ṣe mọ òdodo Ọlọ́run,+ àmọ́ tó jẹ́ pé bí wọ́n á ṣe gbé tiwọn kalẹ̀ ni wọ́n ń wá,+ wọn ò fi ara wọn sábẹ́ òdodo Ọlọ́run.+