46 Nígbà tó ṣì ń bá àwọn èrò náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀+ dúró síta, wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa bá a sọ̀rọ̀.+47 Ẹnì kan wá sọ fún un pé: “Wò ó! Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró níta, wọ́n fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”
31 Ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀+ wá, wọ́n dúró síta, wọ́n sì ní kí ẹnì kan lọ pè é wá.+32 Torí àwọn èrò jókòó yí i ká, wọ́n sọ fún un pé: “Wò ó! Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ wà níta, wọ́n ń béèrè rẹ.”+