-
Mátíù 9:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Wò ó! obìnrin kan tí ìsun ẹ̀jẹ̀+ ti ń yọ lẹ́nu fún ọdún méjìlá (12) sún mọ́ ọn láti ẹ̀yìn, ó sì fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ 21 torí ó ń sọ fún ara rẹ̀ ṣáá, pé: “Tí mo bá ṣáà ti fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ara mi á yá.” 22 Jésù yíjú pa dà, nígbà tó rí i, ó sọ pé: “Mọ́kàn le, ọmọbìnrin! Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ Láti wákàtí yẹn, ara obìnrin náà yá.+
-
-
Máàkù 5:25-29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Obìnrin kan wà tó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀+ fún ọdún méjìlá (12).+ 26 Ó ti jìyà gan-an* lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ oníṣègùn, ó sì ti ná gbogbo ohun tó ní, àmọ́ kàkà kí ara rẹ̀ yá, ṣe ló ń burú sí i. 27 Nígbà tó gbọ́ ìròyìn nípa Jésù, ó gba àárín èrò wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ 28 torí ó ń sọ ṣáá pé: “Tí mo bá fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi á yá.”+ 29 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gbẹ láú, ó sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àìsàn burúkú tó ń ṣe òun ti lọ.
-