-
Máàkù 6:14-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ọba Hẹ́rọ́dù wá gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, torí òkìkí orúkọ Jésù ti kàn káàkiri, àwọn èèyàn sì ń sọ pé: “A ti jí Jòhánù Onírìbọmi dìde, ìdí nìyẹn tó fi lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí.”+ 15 Àmọ́ àwọn míì ń sọ pé: “Èlíjà ni.” Síbẹ̀, àwọn míì ń sọ pé: “Ó dà bí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́.”+ 16 Àmọ́ nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́, ó sọ pé: “Jòhánù tí mo bẹ́ lórí, òun ló ti jíǹde yìí.”
-