ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 14:1-5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ní àkókò yẹn, Hẹ́rọ́dù, alákòóso agbègbè náà,* gbọ́ ìròyìn nípa Jésù,+ 2 ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Jòhánù Arinibọmi nìyí. A ti jí i dìde, ìdí sì nìyẹn tó fi lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí.”+ 3 Hẹ́rọ́dù* ti mú Jòhánù, ó dè é, ó sì fi sẹ́wọ̀n torí Hẹrodíà, ìyàwó Fílípì arákùnrin rẹ̀.+ 4 Jòhánù sì ti ń sọ fún un pé: “Kò bófin mu fún ọ láti fẹ́ obìnrin yìí.”+ 5 Àmọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ pa á, ó ń bẹ̀rù àwọn èèyàn, torí pé wòlíì ni wọ́n kà á sí.+

  • Lúùkù 9:7-9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Hẹ́rọ́dù* alákòóso agbègbè náà* wá gbọ́ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀ rárá torí àwọn kan ń sọ pé a ti jí Jòhánù dìde,+ 8 àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà ti fara hàn, àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ti dìde.+ 9 Hẹ́rọ́dù sọ pé: “Mo ti bẹ́ Jòhánù lórí.+ Ta wá ni ẹni tí mò ń gbọ́ àwọn nǹkan yìí nípa rẹ̀?” Torí náà, ó ń wá bó ṣe máa rí i.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́