ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Dáníẹ́lì 7:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 “‘A sì fún àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ ní ìjọba, àkóso àti títóbi àwọn ìjọba lábẹ́ gbogbo ọ̀run.+ Ìjọba tó máa wà títí láé ni ìjọba wọn,+ gbogbo ìjọba á máa sìn wọ́n, wọ́n á sì máa ṣègbọràn sí wọn.’

  • Lúùkù 22:28-30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin lẹ ti dúró tì mí+ nígbà àdánwò;+ 29 mo sì bá yín dá májẹ̀mú fún ìjọba kan, bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú,+ 30 kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ní tábìlì mi nínú Ìjọba mi,+ kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́+ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì.+

  • Hébérù 12:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Torí náà, bí a ṣe rí i pé a máa tẹ́wọ́ gba Ìjọba kan tí kò ṣeé mì, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, èyí tí a lè tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ọ̀wọ̀.

  • Jémíìsì 2:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n. Ṣebí àwọn tí aráyé kà sí tálákà ni Ọlọ́run yàn pé kí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́+ àti ajogún Ìjọba náà, èyí tó ṣèlérí fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?+

  • Ìfihàn 1:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 tó sì mú ká di ìjọba kan,+ àlùfáà+ fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀—àní, òun ni kí ògo àti agbára jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́