Mátíù 24:44 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 44 Torí èyí, kí ẹ̀yin náà múra sílẹ̀,+ torí wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó máa jẹ́ ni Ọmọ èèyàn ń bọ̀. Mátíù 25:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 “Torí náà, ẹ máa ṣọ́nà,+ torí pé ẹ ò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.+ Ìfihàn 3:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Torí náà, máa fi bí o ṣe gbà àti bí o ṣe gbọ́ sọ́kàn,* kí o máa pa á mọ́, kí o sì ronú pìwà dà.+ Bí o ò bá jí, ó dájú pé màá wá bí olè,+ o ò sì ní mọ wákàtí tí màá dé bá ọ rárá.+
3 Torí náà, máa fi bí o ṣe gbà àti bí o ṣe gbọ́ sọ́kàn,* kí o máa pa á mọ́, kí o sì ronú pìwà dà.+ Bí o ò bá jí, ó dájú pé màá wá bí olè,+ o ò sì ní mọ wákàtí tí màá dé bá ọ rárá.+