-
Mátíù 24:48-51Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
48 “Àmọ́ tí ẹrú burúkú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi ń pẹ́,’+ 49 tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú, tó ń jẹ, tó sì ń mu pẹ̀lú àwọn ọ̀mùtí paraku, 50 ọ̀gá ẹrú yẹn máa dé ní ọjọ́ tí kò retí àti wákàtí tí kò mọ̀,+ 51 ó máa fi ìyà tó le jù lọ jẹ ẹ́, ó sì máa fi í sí àárín àwọn alágàbàgebè. Ibẹ̀ ni á ti máa sunkún, tí á sì ti máa payín keke.+
-