-
Mátíù 18:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Kí lèrò yín? Tí ọkùnrin kan bá ní ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, tí ọ̀kan nínú wọn sì sọ nù,+ ṣebí ó máa fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ lórí òkè ni, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá èyí tó sọ nù?+ 13 Tó bá sì rí i, mò ń sọ fún yín, ó dájú pé ó máa yọ̀ gidigidi torí rẹ̀ ju mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) tí kò tíì sọ nù.
-