ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 34:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 “Màá wá èyí tó sọ nù,+ màá mú èyí tó rìn lọ pa dà wálé, màá fi aṣọ wé èyí tó fara pa, màá sì tọ́jú èyí tó rẹ̀ kó lè lágbára; àmọ́ èmi yóò pa èyí tó sanra àti èyí tó lágbára. Èmi yóò dá a lẹ́jọ́.”

  • Mátíù 9:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Torí náà, ẹ lọ kọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí: ‘Àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ.’+ Torí kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”

  • Mátíù 15:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Ó fèsì pé: “A kò rán mi sí ẹnikẹ́ni àfi àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.”+

  • Lúùkù 15:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 “Ọkùnrin wo nínú yín, tó ní ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, ló jẹ́ pé tí ọ̀kan nínú wọn bá sọ nù, kò ní fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ nínú aginjù, kó sì wá èyí tó sọ nù lọ títí ó fi máa rí i?+

  • Róòmù 5:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Àmọ́ Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ rẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.+

  • 1 Tímótì 1:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, ó sì yẹ ká gbà á délẹ̀délẹ̀, pé: Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là.+ Èmi sì ni ẹni àkọ́kọ́ lára wọn.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́