5 Àwọn méjìlá (12) yìí ni Jésù rán jáde, ó fún wọn ní àwọn ìtọ́ni yìí:+ “Ẹ má lọ sí ojú ọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ má sì wọ ìlú Samáríà kankan;+6 kàkà bẹ́ẹ̀, léraléra ni kí ẹ máa lọ sọ́dọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.+
26 Ẹ̀yin ni Ọlọ́run kọ́kọ́ rán Ìránṣẹ́ rẹ̀ sí,+ lẹ́yìn tí ó gbé e dìde, kí ó lè bù kún yín láti mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín yí pa dà kúrò nínú àwọn iṣẹ́ ibi rẹ̀.”
46 Ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bá fi ìgboyà sọ fún wọn pé: “Ó pọn dandan pé ẹ̀yin ni kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún.+ Nígbà tí ẹ sì ti kọ̀ ọ́, tí ẹ ò ka ara yín sí ẹni tó yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, torí náà, a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè.+