-
Ìṣe 13:45, 46Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
45 Nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ èèyàn, inú bí wọn* gidigidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ òdì ta ko àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.+ 46 Ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bá fi ìgboyà sọ fún wọn pé: “Ó pọn dandan pé ẹ̀yin ni kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún.+ Nígbà tí ẹ sì ti kọ̀ ọ́, tí ẹ ò ka ara yín sí ẹni tó yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, torí náà, a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè.+
-